BRIEF HISTORY OF ILARO

 670 total views,  2 views today

ÌTÀN ÌLÚ ILARO

Nígbàtí ìdààmú àwọn ajínigbé láti ìlú Dahomey pò jù ní àwọn ògbójú ọdẹ àti jagunjagun bí mélòó kan bá parapò láti dáàbòbo agbègbè wọn.
Báyìí ní jagunjagun kán tí orúkọ rè njé Aro láti ìlú Oyo pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rè se dá ibùdó ogun sílè nínú Igbó Ajé ní nǹkan bi òrúndún méjìdínlógún (18th century) láti inú igbó ajé yìí ní Aro àti àwọn ọmọ ogun rè ti ń lé òtá padà. Báyìí ní ibùgbé yìí se di Ìlú Aro títí tí àpẹ̀ bàjé rè fí wa di “Ilaro” tí a mò sí ní òde òní.

Ìtàn fi yé wa wípé ìlú Ilaro ojóun kún fún àwọn àgbẹ̀ nlá, ọdẹ àti jagunjagun ní nínú wọn ni Orona àti Osata. Ìtàn náà tèsíwájú wípé Òròna jé alágbára nlá kán tí ó sé ìdáàbòbò tó dáa tó fún àwọn ènìyàn rè sùgbón ní àsìkò tí Òròna dàgbà tí ódi ògbó tí ó fé rẹ ibi àgbà mí rẹ̀ẹ̀ Orona wo inú ilé lọ tóun tí Ẹkùn (Leopard) rè sùgbón kí ó tó wọ inú ilé lọ ó wí fún àwọn ènìyàn rè wípé ní àsìkò ìpọ́njú àti ìdààmú kí wón ké pe òun nípa fífaa okùn tí a sọ mọ́ ara rẹ̀ àti ẹkùn náà.

Agbègbè tí Orona wọ inú ilé yìí ní ojúbo òrìsà Orona ní ìlú Ilaro ibè sì ní àwọn Ọba tí ó bá jẹ ní ìlú náà tí n gba adé. Ilé ìwé gíga Federal Polytechnic wà ní ìlú Ilaro.

Àwòrán yìí jé ti Ẹ̀re jagunjagun, Òròna pẹ̀lú Ẹkùn rè ní ìlú Ilaro.

Sé èyin ti dé ìlú Ilaro rí?

Source: Yoruba blog

Be the first to comment

Leave a Reply

Your email address will not be published.


*